Peteru si tẹjumọ́ ọ, pẹlu Johanu, o ni, Wò wa. O si fiyesi wọn, o nreti ati ri nkan gbà lọwọ wọn. Peteru wipe, Fadakà ati wura emi kò ni; ṣugbọn ohun ti mo ni eyini ni mo fifun ọ: Li orukọ Jesu Kristi ti Nasareti, dide ki o si mã rin. O si fà a li ọwọ́ ọtún, o si gbé e dide: li ojukanna ẹsẹ rẹ̀ ati egungun kokosẹ rẹ̀ si mokun. O si nfò soke, o duro, o si bẹrẹ si rin, o si ba wọn wọ̀ inu tẹmpili lọ, o nrìn, o si nfò, o si nyìn Ọlọrun. Gbogbo enia si ri i, o nrìn, o si nyìn Ọlọrun
Kà Iṣe Apo 3
Feti si Iṣe Apo 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 3:4-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò