Iṣe Apo 3:17-20

Iṣe Apo 3:17-20 YBCV

Njẹ nisisiyi, ará, mo mọ̀ pe, nipa aimọ̀ li ẹnyin fi ṣe e, gẹgẹ bi awọn olori nyin pẹlu ti ṣe. Ṣugbọn ohun ti Ọlọrun ti sọ tẹlẹ lati ẹnu gbogbo awọn woli wá pe, Kristi rẹ̀ yio jìya, on li o muṣẹ bẹ̃. Nitorina ẹ ronupiwada, ki ẹ si tun yipada, ki a le pa ẹ̀ṣẹ nyin rẹ́, ki akoko itura ba le ti iwaju Oluwa wá, Ati ki o ba le rán Kristi, ti a ti yàn fun nyin, aní Jesu