Iṣe Apo 28:8-10

Iṣe Apo 28:8-10 YBCV

O si ṣe, baba Publiu dubulẹ arùn ibà ati ọ̀rin: ẹniti Paulu wọle tọ̀ lọ, ti o si gbadura fun, nigbati o si fi ọwọ́ le e, o mu u larada. Nigbati eyi si ṣe tan, awọn iyokù ti o li arùn li erekuṣu na, tọ̀ ọ wá, o si mu wọn larada: Awọn ẹniti o bù ọlá pipọ fun wa; nigbati awa si nlọ, nwọn dì nkan gbogbo rù wa ti a ba ṣe alaini.