Li àgbegbe ibẹ̀ ni ilẹ ọkunrin ọlọlá erekuṣu na wà, orukọ ẹniti a npè ni Publiu; ẹniti o gbà wa si ọdọ, ti o si fi inu rere mu wa wọ̀ ni ijọ mẹta. O si ṣe, baba Publiu dubulẹ arùn ibà ati ọ̀rin: ẹniti Paulu wọle tọ̀ lọ, ti o si gbadura fun, nigbati o si fi ọwọ́ le e, o mu u larada. Nigbati eyi si ṣe tan, awọn iyokù ti o li arùn li erekuṣu na, tọ̀ ọ wá, o si mu wọn larada: Awọn ẹniti o bù ọlá pipọ fun wa; nigbati awa si nlọ, nwọn dì nkan gbogbo rù wa ti a ba ṣe alaini. Ati lẹhin oṣù mẹta awa wọ̀ ọkọ Aleksandria kan, ti o lo akoko otutu li erekuṣu na, àmi eyi ti iṣe Kastoru on Poluksu. Nigbati awa gúnlẹ ni Sirakuse, awa gbé ibẹ̀ ni ijọ mẹta. Lati ibẹ̀ nigbati awa lọ yiká, awa de Regioni: ati lẹhin ijọ kan afẹfẹ gusù dide, ni ijọ keji rẹ̀ awa si de Puteoli, Nibiti a gbé ri awọn arakunrin, ti nwọn si bẹ̀ wa lati ba wọn gbé ni ijọ meje: bẹ̃li awa si lọ si ìha Romu. Ati lati ibẹ nigbati awọn arakunrin gburó wa, nwọn wá titi nwọn fi de Apii Foroni, ati Arojẹ mẹta, lati pade wa: nigbati Paulu si ri wọn, o dupẹ lọwọ Ọlọrun, o mu ọkàn le.
Kà Iṣe Apo 28
Feti si Iṣe Apo 28
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 28:7-15
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò