Iṣe Apo 28:3-6

Iṣe Apo 28:3-6 YBCV

Nigbati Paulu si ṣà ìdi iwọ́nwọ́n igi jọ, ti o si kó o sinu iná, pamọlẹ kan ti inu oru jade, o dì mọ́ ọ li ọwọ́. Bi awọn alaigbede na si ti ri ẹranko oloró na ti dì mọ́ ọ li ọwọ́, nwọn ba ara wọn sọ pe, Dajudaju apania li ọkunrin yi, ẹniti o yọ ninu okun tan, ṣugbọn ti ẹsan kò si jẹ ki o wà lãye. On si gbọ̀n ẹranko na sinu iná, ohunkohun kan kò ṣe e. Ṣugbọn nwọn nwoye igbati yio wú, tabi ti yio si ṣubu lulẹ kú lojiji: nigbati nwọn wò titi, ti nwọn kò si ri nkankan ki o ṣe e, nwọn pa iyè da pe, oriṣa kan li ọkunrin yi.