Iṣe Apo 27:18-21

Iṣe Apo 27:18-21 YBCV

Bi awa si ti nṣe lãlã gidigidi ninu ìji na, ni ijọ keji nwọn kó nkan dà si omi lati mu ọkọ̀ fẹrẹ; Ati ni ijọ kẹta, a fi ọwọ́ ara wa kó ohun èlo ọkọ̀ danu. Nigbati õrùn ati irawọ kò si hàn li ọjọ pipọ, ti ìji na kò si mọ̀ niwọn fun wa, abá a-ti-là kò si fun wa mọ́. Nigbati nwọn wà ni aijẹun li ọjọ pipọ, nigbana Paulu dide larin wọn, o ni, Alàgba, ẹnyin iba ti gbọ́ ti emi, ki a máṣe ṣikọ̀ kuro ni Krete, ewu ati òfo yi kì ba ti ba wa.