Iṣe Apo 27:13-15

Iṣe Apo 27:13-15 YBCV

Nigbati afẹfẹ gusù si nfẹ jẹ́jẹ, ti nwọn ṣebi ọwọ awọn tẹ̀ ohun ti nwọn nwá, nwọn ṣikọ̀, nwọn npá ẹba Krete lọ. Kò si pẹ lẹhin na ni ìji ti a npè ni Eurakuilo fẹ lù u. Nigbati o si ti gbé ọkọ̀, ti kò si le dojukọ ìji na, awa jọwọ rẹ̀, o ngbá a lọ.