Iṣe Apo 25:10-11

Iṣe Apo 25:10-11 YBCV

Paulu si wipe, Niwaju itẹ́ idajọ Kesari ni mo duro nibiti o yẹ ki a ṣe ẹjọ mi: emi kò ṣẹ awọn Ju, bi iwọ pẹlu ti mọ̀ daju. Njẹ bi mo ba ṣẹ̀, ti mo si ṣe ohun kan ti o yẹ fùn ikú, emi kò kọ̀ lati kú: ṣugbọn bi kò ba si nkan wọnni ninu ohun ti awọn wọnyi fi mi sùn si, ẹnikan kò le fi mi ṣe oju're fun wọn. Mo fi ọ̀ran mi lọ Kesari.