Iṣe Apo 25:1-4

Iṣe Apo 25:1-4 YBCV

NJẸ nigbati Festu de ilẹ na, lẹhin ijọ mẹta o gòke lati Kesarea lọ si Jerusalemu. Awọn olori alufa ati awọn enia pataki ninu awọn Ju fi Paulu sùn u, nwọn si bẹ̀ ẹ, Nwọn nwá oju're rẹ̀ si Paulu, ki o le ranṣẹ si i wá si Jerusalemu: nwọn ndèna dè e lati pa a li ọna. Ṣugbọn Festu dahun pe, a pa Paulu mọ́ ni Kesarea, ati pe on tikara on nmura ati pada lọ ni lọ̃lọ̃yi.