Ṣugbọn lẹhin ijọ melokan, Feliksi de ti on ti Drusilla obinrin rẹ̀, ti iṣe Ju, o si ranṣẹ pè Paulu, o si gbọ́ ọ̀rọ lọdọ rẹ̀ nipa igbagbọ́ ninu Kristi Jesu. Bi o si ti nsọ asọye nipa ti ododo ati airekọja ati idajọ ti mbọ̀, ẹ̀ru ba Feliksi, o dahùn wipe, Mã lọ nisisiyi na; nigbati mo ba si ni akokò ti o wọ̀, emi o ranṣẹ pè ọ. O si nreti pẹlu pe a ba fun on li owo lati ọwọ́ Paulu wá, ki on ki o le da a silẹ: nitorina a si ma ranṣẹ si i nigbakugba, a ma ba a sọ̀rọ. Ṣugbọn lẹhin ọdún meji, Porkiu Festu rọpò Feliksi: Feliksi si nfẹ ṣe oju're fun awọn Ju, o fi Paulu silẹ li ondè.
Kà Iṣe Apo 24
Feti si Iṣe Apo 24
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 24:24-27
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò