LẸHIN ijọ marun Anania olori alufa ni sọkalẹ lọ pẹlu awọn alàgba ati ẹnikan Tertulu agbẹjọrò ẹniti o fi Paulu sùn bãlẹ. Nigbati a si ti pè e jade, Tertulu bẹ̀rẹ si ifi i sùn wipe, Bi o ti jẹ pe nipasẹ rẹ li awa njẹ alafia pipọ, ati pe nipasẹ itọju rẹ a nṣe atunṣe fun orilẹ yi. Nigbagbogbo, ati nibigbogbo, li awa nfi gbogbo ọpẹ́ tẹwọgbà a, Feliksi ọlọla julọ. Ṣugbọn ki emi ki o má bà da ọ duro pẹ titi, mo bẹ̀ ọ ki o fi iyọnu rẹ gbọ́ ọ̀rọ diẹ li ẹnu wa. Nitori awa ri ọkunrin yi, o jẹ onijagidi enia, ẹniti o ndá rukerudo silẹ lãrin gbogbo awọn Ju ti o wà ni gbogbo aiye, ati olori ẹ̀ya awọn Nasarene: Ẹniti o gbidanwo lati bà tẹmpili jẹ: ti awa si mu, ti awa fẹ ba ṣe ẹjọ gẹgẹ bi ofin wa. Ṣugbọn Lisia olori ogun de, o fi agbara nla gbà a li ọwọ wa: O paṣẹ ki awọn olufisùn rẹ̀ wá sọdọ rẹ: lati ọdọ ẹniti iwọ ó le ni oye gbogbo nkan wọnyi, nitori ohun ti awa ṣe fi i sùn nigbati iwọ ba ti wadi ẹjọ rẹ̀. Awọn Ju pẹlu si fi ohùn si i, wipe, bẹ̃ni nkan wọnyi ri.
Kà Iṣe Apo 24
Feti si Iṣe Apo 24
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 24:1-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò