O si pè meji awọn balogun ọrún sọdọ rẹ̀, o si wipe, Ẹ mura igba ọmọ-ogun silẹ, lati lọ si Kesarea, ati adọrin ẹlẹṣin, ati igba ọlọkọ̀, ni wakati kẹta oru;
O si wipe, ki nwọn pèse ẹranko, ki nwọn gbé Paulu gùn u, ki nwọn si le mu u de ọdọ Feliksi bãlẹ li alafia.
O si kọ iwe kan bayi pe:
Klaudiu Lisia si Feliksi bãlẹ ọlọla julọ, alafia.
Awọn Ju mu ọkunrin yi, nwọn si npete ati pa a: nigbana ni mo de pẹlu ogun, mo si gbà a lọwọ wọn nigbati mo gbọ́ pe ara Romu ni iṣe.
Nigbati mo si nfẹ mọ̀ idi ọ̀ran ti nwọn fi i sùn si, mo mu u sọkalẹ lọ si ajọ igbimọ wọn:
Ẹniti mo ri pe, nwọn fisùn nitori ọ̀ran ofin wọn, bẹ̃ni kò dà ọ̀ran kan ti o tọ́ si ikú ati si ìde.
Nigbati a si ti sọ fun mi pe, nwọn ó dèna dè ọkunrin na, ọgan mo si rán a si ọ, mo si paṣẹ fun awọn olufisùn rẹ̀ pẹlu, lati sọ ohun ti nwọn ba ri wi si i niwaju rẹ.
Nigbana li awọn ọmọ-ogun gbà Paulu, nwọn si mu u li oru lọ si Antipatri, gẹgẹ bi a ti paṣẹ fun wọn.
Nijọ keji nwọn si jọwọ awọn ẹlẹṣin lati mã ba a lọ, nwọn si pada wá sinu ile-olodi.
Nigbati nwọn de Kesarea, ti nwọn si fi iwe fun bãlẹ, nwọn mu Paulu pẹlu wá siwaju rẹ̀.
Nigbati o si ti kà iwe na, o bère pe ara ilẹ wo ni iṣe. Nigbati o si gbọ́ pe ara Kilikia ni;
O ni, Emi ó gbọ́ ẹjọ rẹ, nigbati awọn olufisùn rẹ pẹlu ba de. O si paṣẹ pe ki nwọn ki o pa a mọ́ ni gbọ̀ngan idajọ Herodu.