Iṣe Apo 23:10-11

Iṣe Apo 23:10-11 YBCV

Nigbati iyapa si di nla, ti olori ogun bẹ̀ru ki Paulu ki o má bà di fifaya lọwọ wọn, o paṣẹ pe ki awọn ọmọ-ogun sọkalẹ lọ lati fi ipá mu u kuro lãrin wọn, ki nwọn si mu u wá sinu ile-olodi. Li oru ijọ nã Oluwa duro tì i, o si wipe, Tujuka: nitori bi iwọ ti jẹri fun mi ni Jerusalemu, bẹ̃ni iwọ kò le ṣaijẹrí ni Romu pẹlu.