Nwọn si fi etí si i titi de ọ̀rọ yi, nwọn si gbé ohùn wọn soke wipe, Ẹ mu irú eyiyi kuro li aiye: nitori kò yẹ ki o wà lãye. Bi nwọn si ti nkigbe, ti nwọn si wọ́n aṣọ wọn silẹ, ti nwọn nku ekuru si oju ọrun, Olori ogun paṣẹ pe ki a mu u wá sinu ile-olodi, o ni ki a fi ẹgba bi i lẽre; ki on ki o le mọ̀ itori ohun ti nwọn ṣe nkigbe le e bẹ̃. Bi nwọn si ti fi ọsán dè e, Paulu bi balogun ọrún ti o duro tì i pe, O ha tọ́ fun nyin lati nà ẹniti iṣe ará Romu li aijẹbi? Nigbati balogun ọrún si gbọ́, o lọ, o wi fun olori-ogun pe, Kili o fẹ ṣe yi: nitori ọkunrin yi ara Romu ni iṣe. Olori-ogun si de, o si bi i pe, Sọ fun mi, ara Romu ni iwọ iṣe? O si wipe, Bẹ̃ni. Olori-ogun si dahùn wipe, Owo pupọ ni mo fi rà ọlá ibilẹ yi. Paulu si wipe, Ṣugbọn a bí emi bẹ̃ ni. Nitorina awọn ti o mura lati bi i lẽre kuro lọdọ rẹ̀: lojukanna olori-ogun pẹlu si bẹ̀ru, nigbati o mọ̀ pe ara Romu ni iṣe, ati nitori o ti dè e. Ni ijọ keji, nitoriti o fẹ mọ̀ dajudaju ohun ti awọn Ju nfi i sùn si, o tú u silẹ, o paṣẹ ki awọn olori alufa ati gbogbo igbimọ pejọ, o si mu Paulu sọkalẹ, o si mu u duro niwaju wọn.
Kà Iṣe Apo 22
Feti si Iṣe Apo 22
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 22:22-30
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò