Iṣe Apo 20:21-24

Iṣe Apo 20:21-24 YBCV

Ti mo nsọ fun awọn Ju, ati fun awọn Hellene pẹlu, ti ironupiwada sipa Ọlọrun, ati ti igbagbọ́ sipa Jesu Kristi Oluwa wa. Njẹ nisisiyi, wo o, ọkàn mi nfà si ati lọ si Jerusalemu, laimọ̀ ohun ti yio bá mi nibẹ̀: Bikoṣe bi Ẹmí Mimọ́ ti nsọ ni ilu gbogbo pe, ìde on ìya mbẹ fun mi. Ṣugbọn emi kò kà ẹmi mi si nkan rara bi ohun ti o ṣọwọn fun mi, ki emi ki o ba le fi ayọ̀ pari ire-ije mi ati iṣẹ-iranṣẹ ti mo ti gbà lọdọ Jesu Oluwa, lati mã ròhin ihinrere ore-ọfẹ Ọlọrun.