Iṣe Apo 20:1-6

Iṣe Apo 20:1-6 YBCV

NIGBATI ariwo na si rọlẹ, Paulu ranṣẹ pè awọn ọmọ-ẹhin, o si gbà wọn ni iyanju, o dagbere fun wọn, o dide lati lọ si Makedonia. Nigbati o si ti là apa ìha wọnni kọja, ti o si ti fi ọ̀rọ pipọ gbà wọn ni iyanju, o wá si ilẹ Hellene. Nigbati o si duro nibẹ̀ li oṣù mẹta, ti awọn Ju si dèna dè e, bi o ti npete ati ba ti ọkọ̀ lọ si Siria, o pinnu rẹ̀ lati ba ti Makedonia pada lọ. Sopateru ara Berea ọmọ Parru si ba a lọ de Asia; ati ninu awọn ara Tessalonika, Aristarku on Sekundu; ati Gaiu ara Derbe, ati Timotiu; ati ara Asia, Tikiku on Trofimu. Ṣugbọn awọn wọnyi ti lọ ṣiwaju, nwọn nduro dè wa ni Troa. Awa si ṣikọ̀ lati Filippi wá lẹhin ọjọ aiwukara, a si de ọdọ wọn ni Troasi ni ijọ karun; nibiti awa gbé duro ni ijọ meje.