Ará, ẹ jẹ ki emi ki o sọ fun nyin gbangba niti Dafidi baba nla pe, o kú, a si sin i, ibojì rẹ̀ si mbẹ lọdọ wa titi o fi di oni yi. Nitoriti iṣe woli, ati bi o ti mọ̀ pe, Ọlọrun ti fi ibura ṣe ileri fun u pe, Ninu irú-ọmọ inu rẹ̀, on ó mu ọ̀kan ijoko lori itẹ́ rẹ̀; O ri eyi tẹlẹ̀, o sọ ti ajinde Kristi pe, a kò fi ọkàn rẹ̀ silẹ ni ipò-okù, bẹ̃li ara rẹ̀ kò ri idibajẹ. Jesu na yi li Ọlọrun ti ji dide, ẹlẹri eyiti gbogbo wa iṣe. Nitorina bi a ti fi ọwọ́ ọtún Ọlọrun gbe e ga, ti o si ti gbà ileri Ẹmí Mimọ́ lati ọdọ Baba, o tú eyi silẹ, ti ẹnyin ri, ti ẹ si gbọ́. Dafidi kò sá gòke lọ si ọrun: ṣugbọn on tikararẹ̀ wipe, OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Joko li ọwọ́ ọtún mi, Titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apotì itisẹ rẹ. Njẹ ki gbogbo ile Israeli ki o mọ̀ dajudaju pe, Ọlọrun ti fi Jesu na, ti ẹnyin kàn mọ agbelebu, jẹ Oluwa ati Kristi.
Kà Iṣe Apo 2
Feti si Iṣe Apo 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 2:29-36
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò