Iṣe Apo 2:15-18

Iṣe Apo 2:15-18 YBCV

Nitori awọn wọnyi kò mutiyó, bi ẹnyin ti fi pè; wakati kẹta ọjọ sá li eyi. Ṣugbọn eyi li ọ̀rọ ti a ti sọ lati ẹnu woli Joeli wá pe; Ọlọrun wipe, Yio si ṣe ni ikẹhin ọjọ, Emi o tú ninu Ẹmí mi jade sara enia gbogbo: ati awọn ọmọ nyin-ọkunrin ati awọn ọmọ nyin obinrin yio ma sọtẹlẹ, awọn ọdọmọkunrin nyin yio si ma ri iran, awọn arugbo nyin yio si ma lá alá: Ati sara awọn ọmọ-ọdọ mi ọkunrin, ati sara awọn ọmọ-ọdọ mi obinrin li emi o tú ninu Ẹmí mi jade li ọjọ wọnni; nwọn o si ma sọtẹlẹ