Nigbati o si wọ̀ inu sinagogu lọ, o fi igboiya sọ̀rọ li oṣù mẹta, o nfi ọ̀rọ̀ we ọ̀rọ̀, o si nyi wọn lọkan pada si nkan ti iṣe ti ijọba Ọlọrun. Ṣugbọn nigbati ọkàn awọn miran ninu wọn di lile, ti nwọn kò si gbagbọ́, ti nwọn nsọ̀rọ ibi si Ọna na niwaju ijọ enia, o lọ kuro lọdọ wọn, o si yà awọn ọmọ-ẹhin sọtọ̀, o si nsọ asọye li ojojumọ́ ni ile-iwe Tirannu. Eyi nlọ bẹ̃ fun iwọn ọdún meji; tobẹ̃ ti gbogbo awọn ti ngbe Asia gbọ́ ọ̀rọ Jesu Oluwa, ati awọn Ju ati awọn Hellene. Ọlọrun si ti ọwọ́ Paulu ṣe iṣẹ aṣẹ akanṣe, Tobẹ̃ ti a fi nmu gèle ati ibantẹ́ ara rẹ̀ tọ̀ awọn olokunrun lọ, arùn si fi wọn silẹ, ati awọn ẹmi buburu si jade kuro lara wọn.
Kà Iṣe Apo 19
Feti si Iṣe Apo 19
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 19:8-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò