Iṣe Apo 18:5-8

Iṣe Apo 18:5-8 YBCV

Nigbati Sila on Timotiu si ti Makedonia wá, ọrọ na ká Paulu lara, o nfi hàn, o sọ fun awọn Ju pe, Jesu ni Kristi na. Nigbati nwọn si wà li òdi, ti nwọn si nsọrọ-odi, o gbọ̀n aṣọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹ̀jẹ nyin mbẹ lori ara nyin; ọrùn emi mọ́: lati isisiyi lọ emi o tọ̀ awọn Keferi lọ. O si lọ kuro nibẹ̀, o wọ̀ ile ọkunrin kan ti a npè ni Titu Justu, ẹniti o nsìn Ọlọrun ti ile rẹ̀ fi ara mọ́ sinagogu tímọ́tímọ́. Ati Krispu, olori sinagogu, o gbà Oluwa gbọ́ pẹlu gbogbo ile rẹ̀; ati ọ̀pọ ninu awọn ara Korinti, nigbati nwọn gbọ́, nwọn gbagbọ́, a si baptisi wọn.