Iṣe Apo 17:26-29

Iṣe Apo 17:26-29 YBCV

O si ti fi ẹ̀jẹ kanna da gbogbo orilẹ-ede lati tẹ̀do si oju agbaiye, o si ti pinnu akokò ti a yàn tẹlẹ, ati àla ibugbe wọn; Ki nwọn ki o le mã wá Oluwa, boya bi ọkàn wọn ba le fà si i, ti wọn si ri i, bi o tilẹ ṣe pe kò jina si olukuluku wa: Nitori ninu rẹ̀ li awa gbé wà li ãye, ti awa nrìn kiri, ti a si li ẹmí wa; bi awọn kan ninu awọn olorin, ẹnyin tikaranyin ti wipe, Awa pẹlu si jẹ ọmọ rẹ̀. Njẹ bi awa ba ṣe ọmọ Ọlọrun, kò yẹ fun wa ki a rò pe, Iwa-Ọlọrun dabi wura, tabi fadaka, tabi okuta, ti a fi ọgbọ́n ati ihumọ enia ṣe li ọnà.