Iṣe Apo 17:22-29

Iṣe Apo 17:22-29 YBCV

Paulu si dide duro larin Areopagu, o ni, Ẹnyin ará Ateni, mo woye pe li ohun gbogbo ẹ kun fun oniruru isin ju. Nitori bi mo ti nkọja lọ, ti mo wò ohun wọnni ti ẹnyin nsìn, mo si ri pẹpẹ kan ti a kọ akọle yi si, FUN ỌLỌRUN AIMỌ̀. Njẹ ẹniti ẹnyin nsìn li aimọ̀ on na li emi nsọ fun nyin. Ọlọrun na ti o da aiye ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, on na ti iṣe Oluwa ọrun on aiye, kì igbé ile ti a fi ọwọ́ kọ́; Bẹ̃ni a kì ifi ọwọ́ enia sìn i, bi ẹnipe o nfẹ nkan, on li o fi ìye ati ẽmi ati ohun gbogbo fun gbogbo enia, O si ti fi ẹ̀jẹ kanna da gbogbo orilẹ-ede lati tẹ̀do si oju agbaiye, o si ti pinnu akokò ti a yàn tẹlẹ, ati àla ibugbe wọn; Ki nwọn ki o le mã wá Oluwa, boya bi ọkàn wọn ba le fà si i, ti wọn si ri i, bi o tilẹ ṣe pe kò jina si olukuluku wa: Nitori ninu rẹ̀ li awa gbé wà li ãye, ti awa nrìn kiri, ti a si li ẹmí wa; bi awọn kan ninu awọn olorin, ẹnyin tikaranyin ti wipe, Awa pẹlu si jẹ ọmọ rẹ̀. Njẹ bi awa ba ṣe ọmọ Ọlọrun, kò yẹ fun wa ki a rò pe, Iwa-Ọlọrun dabi wura, tabi fadaka, tabi okuta, ti a fi ọgbọ́n ati ihumọ enia ṣe li ọnà.