Iṣe Apo 17:2-4

Iṣe Apo 17:2-4 YBCV

Ati Paulu, gẹgẹbi iṣe rẹ̀, o wọle tọ̀ wọn lọ, li ọjọ isimi mẹta o si mba wọn fi ọ̀rọ we ọ̀rọ ninu iwe-mimọ́, O ntumọ, o si nfihàn pe, Kristi kò le ṣaima jìya, ki o si jinde kuro ninu okú; ati pe, Jesu yi, ẹniti emi nwasu fun nyin, on ni Kristi na. A si yi ninu wọn lọkàn pada, nwọn si darapọ̀ mọ́ Paulu on Sila; ati ninu awọn olufọkansìn Hellene ọ̀pọ pupọ, ati ninu awọn obinrin ọlọlá, kì iṣe diẹ.