Nigbati Paulu duro dè wọn ni Ateni, ọkàn rẹ̀ rú ninu rẹ̀, nigbati o ri pe ilu na kún fun oriṣa. Nitorina o mba awọn Ju fi ọ̀rọ̀ we ọ̀rọ̀ ninu sinagogu, ati awọn olufọkansin, ati awọn ti o mba pade lọja lojojumọ. Ninu awọn Epikurei pẹlu, ati awọn ọjọgbọ́n Stoiki kótì i. Awọn kan si nwipe, Kili alahesọ yi yio ri wi? awọn miran si wipe, O dabi oniwasu ajeji oriṣa: nitoriti o nwasu Jesu, on ajinde fun wọn. Nwọn si mu u, nwọn si fà a lọ si Areopagu, nwọn wipe, A ha le mọ̀ kili ẹkọ́ titun ti iwọ nsọrọ rẹ̀ yi jẹ́. Nitoriti iwọ mu ohun ajeji wá si etí wa: awa si nfẹ mọ̀ kini itumọ nkan wọnyi. Nitori gbogbo awọn ará Ateni, ati awọn alejò ti nṣe atipo nibẹ kì iṣe ohun miran jù, ki a mã sọ tabi ki a ma gbọ́ ohun titun lọ.
Kà Iṣe Apo 17
Feti si Iṣe Apo 17
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 17:16-21
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò