Iṣe Apo 16:6-10

Iṣe Apo 16:6-10 YBCV

Nwọn si là ẹkùn Frigia já, ati Galatia, ti a ti ọdọ Ẹmí Mimọ́ kọ̀ fun wọn lati sọ ọ̀rọ na ni Asia. Nigbati nwọn de ọkankan Misia, nwọn gbé e wò lati lọ si Bitinia: ṣugbọn Ẹmí Jesu kò gbà fun wọn. Nigbati nwọn si kọja lẹba Misia, nwọn sọkalẹ lọ si Troasi. Iran kan si hàn si Paulu li oru: ọkunrin kan ara Makedonia duro, o si mbẹ̀ ẹ, wipe, Rekọja wá si Makedonia, ki o si ran wa lọwọ. Nigbati o si ti ri iran na, lọgán awa mura lati lọ si Makedonia, a si gbà pe, Oluwa ti pè wa lati wasu ihinrere fun wọn.