Iṣe Apo 16:26-30

Iṣe Apo 16:26-30 YBCV

Lojiji iṣẹlẹ nla si ṣẹ̀, tobẹ̃ ti ipilẹ ile tubu mi titi: lọgan gbogbo ilẹkun si ṣí, ìde gbogbo wọn si tu silẹ. Nigbati onitubu si tají, ti o si ri pe, awọn ikẹkun tubu ti ṣí silẹ, o fà idà rẹ̀ yọ, o si fẹ pa ara rẹ̀, o ṣebi awọn ara tubu ti sá lọ. Ṣugbọn Paulu kọ kàrá, wipe, Máṣe pa ara rẹ lara: nitori gbogbo wa mbẹ nihinyi. Nigbati o si bere iná, o bẹ́ sinu ile, o nwariri, o wolẹ niwaju Paulu on Sila. O si mu wọn jade, o ni, Alàgba, kini ki emi ki o ṣe ki ng le là?