O si ṣe, bi awa ti nlọ si ibi adura na, ọmọbinrin kan ti o li ẹmi afọṣẹ, pade wa, ẹniti o fi afọṣẹ mu ère pipọ fun awọn oluwa rẹ̀ wá: On na li o ntọ̀ Paulu ati awa lẹhin, o si nkigbe, wipe, Awọn ọkunrin wọnyi ni iranṣẹ Ọlọrun Ọgá-ogo, ti nkede ọ̀na igbala fun nyin. O si nṣe eyi li ọjọ pipọ. Ṣugbọn nigbati inu Paulu bajẹ, ti o si yipada, o wi fun ẹmí na pe, Mo paṣẹ fun ọ li orukọ Jesu Kristi kí o jade kuro lara rẹ̀. O si jade ni wakati kanna. Nigbati awọn oluwa rẹ̀ si ri pe, igbẹkẹle ère wọn pin, nwọn mu Paulu on Sila, nwọn si wọ́ wọn lọ si ọjà tọ̀ awọn ijoye lọ; Nigbati nwọn si mu wọn tọ̀ awọn onidajọ lọ, nwọn wipe, Awọn ọkunrin wọnyi ti iṣe Ju, nwọn nyọ ilu wa lẹnu jọjọ; Nwọn si nkọni li àṣa ti kò yẹ fun wa, awa ẹniti iṣe ara Romu, lati gbà, ati lati tẹle. Ọpọ enia si jumọ dide si wọn: awọn olori si fà wọn li aṣọ ya, nwọn si paṣẹ pe, ki a fi ọgọ lù wọn.
Kà Iṣe Apo 16
Feti si Iṣe Apo 16
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 16:16-22
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò