Iṣe Apo 15:6-11

Iṣe Apo 15:6-11 YBCV

Ati awọn aposteli ati awọn àgbagbà pejọ lati gbìmọ ọ̀ran yi. Nigbati iyàn si di pipọ, Peteru dide, o si wi fun wọn pe, Ará, ẹnyin mọ̀ pe, lati ibẹrẹ Ọlọrun ti yàn ninu nyin, ki awọn Keferi ki o le gbọ́ ọ̀rọ ihinrere li ẹnu mi, ki nwọn si gbagbọ́. Ati Ọlọrun, ti iṣe olumọ-ọkàn, o jẹ wọn li ẹrí, o nfun wọn li Ẹmí Mimọ́, gẹgẹ bi awa: Kò si fi iyatọ si ãrin awa ati awọn, o nfi igbagbọ́ wẹ̀ wọn li ọkàn mọ́. Njẹ nitorina ẽṣe ti ẹnyin o fi dán Ọlọrun wò, lati fi àjaga bọ̀ awọn ọmọ-ẹhin li ọrùn, eyiti awọn baba wa ati awa kò le rù? Ṣugbọn awa gbagbọ́ pe nipa ore-ọfẹ Oluwa Jesu awa ó là, gẹgẹ bi awọn.