Iṣe Apo 15:28-29

Iṣe Apo 15:28-29 YBCV

Nitori o dara loju Ẹmi Mimọ́, ati loju wa, ki a máṣe dì ẹrù kà nyin, jù nkan ti a ko le ṣe alaiṣe wọnyi lọ: Ki ẹnyin ki o fà sẹhin kuro ninu ẹran apabọ oriṣa, ati ninu ẹ̀jẹ ati ninu ohun ilọlọrun-pa, ati ninu àgbere: ninu ohun ti, bi ẹnyin ba pa ara nyin mọ́ kuro, ẹnyin ó ṣe rere. Alafia.