Nigbati nwọn si ti wasu ihinrere fun ilu na, ti nwọn si ni ọmọ-ẹ̀hin pupọ, nwọn pada lọ si Listra, ati Ikonioni, ati si Antioku. Nwọn nmu awọn ọmọ-ẹhin li ọkàn le, nwọn ngbà wọn niyanju lati duro ni igbagbọ́, ati pe ninu ipọnju pipọ li awa o fi wọ̀ ijọba Ọlọrun. Nigbati nwọn si ti yàn awọn àgbagba fun olukuluku ijọ, ti nwọn si ti fi àwẹ gbadura, nwọn fi wọn le Oluwa lọwọ, ẹniti nwọn gbagbọ́.
Kà Iṣe Apo 14
Feti si Iṣe Apo 14
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 14:21-23
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò