O si ṣe, ni Ikonioni, nwọn jumọ wọ̀ inu sinagogu awọn Ju lọ, nwọn si sọrọ tobẹ̃, ti ọ̀pọlọpọ awọn Ju ati awọn Hellene gbagbọ́. Ṣugbọn awọn alaigbagbọ́ Ju rú ọkàn awọn Keferi soke, nwọn si rọ̀ wọn si awọn arakunrin na. Nitorina nwọn gbe ibẹ̀ pẹ, nwọn nfi igboiya sọrọ ninu Oluwa, ẹniti o jẹri si ọ̀rọ ore-ọfẹ rẹ̀, o si nyọnda ki iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu mã ti ọwọ́ wọn ṣe. Ṣugbọn ọ̀pọ enia ilu na pin meji: apakan si dàpọ mọ́ awọn Ju, apakan si dàpọ mọ́ awọn aposteli. Bi awọn Keferi, ati awọn Ju pẹlu awọn olori wọn ti fẹ kọlù wọn lati ṣe àbuku si wọn, ati lati sọ wọn li okuta, Nwọn mọ̀, nwọn si sá lọ si Listra ati Derbe ilu Likaonia, ati si àgbegbe ti o yiká: Nibẹ̀ ni nwọn si nwasu ihinrere. Ọkunrin kan si joko ni Listra, ẹniti ẹsẹ rẹ̀ kò mokun, arọ lati inu iya rẹ̀ wá, ti kò rìn ri. Ọkunrin yi gbọ́ bi Paulu ti nsọ̀rọ: ẹni, nigbati o tẹjumọ́ ọ, ti o si ri pe, o ni igbagbọ́ fun imularada, O wi fun u li ohùn rara pe, Dide duro ṣanṣan li ẹsẹ rẹ. O si nfò soke o si nrìn.
Kà Iṣe Apo 14
Feti si Iṣe Apo 14
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 14:1-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò