Iṣe Apo 13:13-15

Iṣe Apo 13:13-15 YBCV

Nigbati Paulu ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ si ṣikọ̀ ni Pafo, nwọn wá si Perga ni Pamfilia: Johanu si fi wọn silẹ, o si pada lọ si Jerusalemu. Nigbati nwọn si là Perga kọja, nwọn wá si Antioku ni Pisidia, nwọn si wọ̀ inu sinagogu li ọjọ isimi, nwọn si joko. Ati lẹhin kìka iwe ofin ati iwe awọn woli, awọn olori sinagogu ranṣẹ si wọn, pe, Ará, bi ẹnyin ba li ọ̀rọ iyanju kan fun awọn enia, ẹ sọ ọ.