Nigbati o si rò o, o lọ si ile Maria iya Johanu, ti apele rẹ̀ jẹ Marku; nibiti awọn enia pipọ pejọ si, ti nwọn ngbadura. Bi o si ti kàn ilẹkun ẹnu-ọ̀na ọmọbinrin kan ti a npè ni Roda, o wá dahun. Nigbati o si ti mọ̀ ohùn Peteru, kò ṣí ilẹkun fun ayọ̀, ṣugbọn o sure wọle, o si sọ pe, Peteru duro li ẹnu-ọ̀na. Nwọn si wi fun u pe, Iwọ nṣiwère. Ṣugbọn o tẹnumọ́ ọ gidigidi pe Bẹ̃ni sẹ. Nwọn si wipe, Angẹli rẹ̀ ni. Ṣugbọn Peteru nkànkun sibẹ, nigbati nwọn si ṣí ilẹkun, nwọn ri i, ẹnu si yà wọn. Ṣugbọn o juwọ́ si wọn pe ki nwọn ki o dakẹ, o si ròhin fun wọn bi Oluwa ti mu on jade kuro ninu tubu. O si wipe, Ẹ lọ isọ nkan wọnyi fun Jakọbu, ati awọn arakunrin. Nigbati o si jade, o lọ si ibomiran.
Kà Iṣe Apo 12
Feti si Iṣe Apo 12
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 12:12-17
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò