LI akoko igbana ni Herodu ọba si nawọ́ rẹ̀ lati pọn awọn kan loju ninu ijọ. O si fi idà pa Jakọbu arakunrin Johanu. Nigbati o si ri pe, o dùnmọ awọn Ju, o si nawọ́ mu Peteru pẹlu. O si jẹ ìgba ọjọ àiwukàra. Nigbati o si mu u, o fi i sinu tubu, o fi i le ẹ̀ṣọ́ mẹrin awọn ọmọ-ogun lọwọ lati ma ṣọ ọ; o nrò lati mu u jade fun awọn enia wá lẹhin Irekọja. Nitorina nwọn pa Peteru mọ́ ninu tubu: ṣugbọn ijọ nfi itara gbadura sọdọ Ọlọrun fun u. Nigbati Herodu iba si mu u jade, li oru na Peteru sùn li arin awọn ọmọ-ogun meji, a fi ẹ̀wọn meji de e, ẹ̀ṣọ́ si wà li ẹnu-ọ̀na, nwọn nṣọ́ tubu na. Si wo o, angẹli Oluwa duro tì i, imọlẹ si mọ́ ninu tubu: nigbati o si lù Peteru pẹ́pẹ li ẹgbẹ o ji i, o ni, Dide kánkan. Ẹwọn rẹ̀ si bọ́ silẹ kuro lọwọ rẹ̀. Angẹli na si wi fun u pe, Di àmure, ki o si so salubàta rẹ. O si ṣe bẹ̃. O si wi fun u pe, Da aṣọ rẹ bora, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin.
Kà Iṣe Apo 12
Feti si Iṣe Apo 12
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 12:1-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò