Barnaba si jade lọ si Tarsu lati wá Saulu. Nigbati o si ri i, o mu u wá si Antioku. O si ṣe, fun ọdun kan gbako ni nwọn fi mba ijọ pejọ pọ̀, ti nwọn si kọ́ enia pipọ. Ni Antioku li a si kọ́ pè awọn ọmọ-ẹhin ni Kristian. Li ọjọ wọnni li awọn woli si ti Jerusalemu sọkalẹ wá si Antioku. Nigbati ọkan ninu wọn, ti a npè ni Agabu si dide, o tipa Ẹmi sọ pe, ìyan nla yio mu ká gbogbo aiye: eyiti o si ṣẹ li ọjọ Klaudiu Kesari. Awọn ọmọ-ẹhin si pinnu, olukuluku gẹgẹ bi agbara rẹ̀ ti to, lati rán iranlọwọ si awọn arakunrin ti o wà ni Judea: Eyiti nwọn si ṣe, nwọn si fi i ranṣẹ si awọn àgba lati ọwọ́ Barnaba on Saulu.
Kà Iṣe Apo 11
Feti si Iṣe Apo 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 11:25-30
3 Awọn ọjọ
Kìí ṣe pé ìgbé ayé onígbàgbọ́ ní ọ̀nà kan pàtó tí ó ń gbà ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti gba Krístì. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé a jẹ́ ti Krístì, a ṣì wà nínú ayé yìí (Jòhánù 17:16). ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àlàkalẹ̀ nílò ìmúyàtọ̀ tí ó mú ìdọ́gba bá wíwà wa lójúkorojú nínú ayé pẹ̀lú ìdámọ̀ wa nípa ẹ̀mí. Bíi ẹ̀dá ti ẹ̀mí, a gbọ́dọ̀ ṣe bó ti tọ́.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò