Iṣe Apo 10:13-15

Iṣe Apo 10:13-15 YBCV

Ohùn kan si fọ̀ si i pe, Dide, Peteru; mã pa ki o si mã jẹ. Ṣugbọn Peteru dahùn pe, Agbẹdọ, Oluwa; nitori emi kò jẹ ohun èwọ ati alaimọ́ kan ri. Ohùn kan si tún fọ̀ si i lẹkeji pe, Ohun ti Ọlọrun ba ti wẹ̀nu, iwọ máṣe pè e li èwọ mọ́.