Iṣe Apo 10:10-15

Iṣe Apo 10:10-15 YBCV

Ebi si pa a gidigidi, on iba si jẹun: ṣugbọn nigbati nwọn npèse, o bọ si ojuran, O si ri ọrun ṣí, ohun elo kan si sọkalẹ bi gọgọwú nla, ti a ti igun mẹrẹrin, sọkalẹ si ilẹ. Ninu rẹ̀ li olorijorí ẹranko ẹlẹsẹ mẹrin wà, ati ohun ti nrakò li aiye ati ẹiyẹ oju ọrun. Ohùn kan si fọ̀ si i pe, Dide, Peteru; mã pa ki o si mã jẹ. Ṣugbọn Peteru dahùn pe, Agbẹdọ, Oluwa; nitori emi kò jẹ ohun èwọ ati alaimọ́ kan ri. Ohùn kan si tún fọ̀ si i lẹkeji pe, Ohun ti Ọlọrun ba ti wẹ̀nu, iwọ máṣe pè e li èwọ mọ́.