Nigbati o si ba wọn pejọ, o paṣẹ fun wọn, ki nwọn ki o máṣe kuro ni Jerusalemu, ṣugbọn ki nwọn ki o duro dè ileri Baba, eyiti, o wipe, ẹnyin ti gbọ́ li ẹnu mi: Nitori nitotọ ni Johanu fi omi baptisi; ṣugbọn a o fi Ẹmí Mimọ́ baptisi nyin, kì iṣe ọjọ pupọ lati oni lọ. Nitorina nigbati nwọn si pejọ, nwọn bi i lere pe, Oluwa, lati igbayi lọ iwọ ó ha mu ijọba pada fun Israeli bi? O si wi fun wọn pe, Kì iṣe ti nyin lati mọ̀ akoko tabi ìgba, ti Baba ti yàn nipa agbara on tikararẹ̀. Ṣugbọn ẹnyin ó gbà agbara, nigbati Ẹmí Mimọ́ ba bà le nyin: ẹ o si ma ṣe ẹlẹri mi ni Jerusalemu, ati ni gbogbo Judea, ati ni Samaria, ati titi de opin ilẹ aiye. Nigbati o si ti wi nkan wọnyi, bi nwọn ti nwò, a gbé e soke; awọsanma si gbà a kuro li oju wọn.
Kà Iṣe Apo 1
Feti si Iṣe Apo 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 1:4-9
3 Awọn ọjọ
Ìbí, ikú àti àjíǹde Jésù mú ìròyìn ayọ̀ náà wá. Ìròyìn ayọ̀ yìí ni ó ti yọrí sí ìgbàlà arayé. Nítorí náà, gbogbo ẹni tí a ti gbàlà ni Jésù Olúwa àti Olùgbàlà ti pa á láṣẹ fún láti dìde fún ìgbàlà àwọn ẹlòmíràn nípasẹ̀ ìkéde-ìhìnrere, èyí tíí ṣe pínpín ìròyìn ayọ̀ yìí kan náà fún àwọn ẹlòmíràn tí kò tíì di ẹni ìgbàlà.
12 Days
Conversations With God is a joyous immersion into a more intimate prayer life, emphasizing practical ways to hear God's voice. God wants us to enjoy a running conversation with Him all of our lives—a conversation that makes all the difference in direction, relationships, and purpose. This plan is filled with transparent, personal stories about the reaching heart of God. He loves us!
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò