Iṣe Apo 1:13-14

Iṣe Apo 1:13-14 YBCV

Nigbati nwọn si wọle, nwọn lọ si yara oke, nibiti Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu, ati Anderu, ati Filippi, ati Tomasi, Bartolomeu, ati Matiu, Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Simoni Selote, ati Juda arakunrin Jakọbu, gbe wà. Gbogbo awọn wọnyi fi ọkàn kan duro si adura ati si ẹ̀bẹ, pẹlu awọn obinrin, ati Maria iya Jesu ati awọn arakunrin rẹ̀ pẹlu.