Bi nwọn si ti tẹ̀jumọ́ oju ọrun bi o ti nrè oke, kiyesi i, awọn ọkunrin meji alaṣọ àla duro leti ọdọ wọn; Ti nwọn si wipe, Ẹnyin ará Galili, ẽṣe ti ẹ fi duro ti ẹ nwò oju ọrun? Jesu na yi, ti a gbà soke ọrun kuro lọwọ nyin, yio pada bẹ̃ gẹgẹ bi ẹ ti ri i ti o nlọ si ọrun. Nigbana ni nwọn pada ti ori òke ti a npè ni Olifi lọ si Jerusalemu, ti o sunmọ Jerusalemu ni ìwọn ìrin ọjọ isimi kan. Nigbati nwọn si wọle, nwọn lọ si yara oke, nibiti Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu, ati Anderu, ati Filippi, ati Tomasi, Bartolomeu, ati Matiu, Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Simoni Selote, ati Juda arakunrin Jakọbu, gbe wà. Gbogbo awọn wọnyi fi ọkàn kan duro si adura ati si ẹ̀bẹ, pẹlu awọn obinrin, ati Maria iya Jesu ati awọn arakunrin rẹ̀ pẹlu.
Kà Iṣe Apo 1
Feti si Iṣe Apo 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 1:10-14
7 Days
New Year. A New Day. God created these transitions to remind us that He is the God of New Beginnings. If God can speak the world into existence, He can certainly speak into the darkness of your life, creating for you a new beginning. Don’t you just love fresh starts! Just like this reading plan. Enjoy!
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò