II. Tim 2:7-13

II. Tim 2:7-13 YBCV

Gbà ohun ti emi nsọ rò; nitori Oluwa yio fun ọ li òye ninu ohun gbogbo. Ranti Jesu Kristi, ti o jinde kuro ninu okú, lati inu irú-ọmọ Dafidi, gẹgẹ bi ihinrere mi, Ninu eyiti emi nri ipọnju titi dé inu ìde bi arufin; ṣugbọn a kò dè ọ̀rọ Ọlọrun. Nitorina mo nfarada ohun gbogbo nitori ti awọn ayanfẹ, ki awọn na pẹlu le ni igbala ti mbẹ ninu Kristi Jesu pẹlu ogo ainipẹkun. Otitọ li ọrọ na: Nitoripe bi awa ba bá a kú, awa ó si bá a yè: Bi awa ba farada, awa ó si ba a jọba: bi awa ba sẹ́ ẹ, on na yio si sẹ́ wa. Bi awa kò ba gbagbọ́, on duro li olõtọ: nitori on kò le sẹ́ ara rẹ̀.