II. Tim 2:19-22

II. Tim 2:19-22 YBCV

Ṣugbọn ipilẹ Ọlọrun ti o daju duro ṣinṣin, o ni èdidi yi wipe, Oluwa mọ̀ awọn ti iṣe tirẹ̀. Ati pẹlu, ki olukuluku ẹniti npè orukọ Oluwa ki o kuro ninu aiṣododo. Ṣugbọn ninu ile nla, kì iṣe kìki ohun elo wura ati ti fadaka nikan ni mbẹ nibẹ̀, ṣugbọn ti igi ati ti amọ̀ pẹlu; ati omiran si ọlá, ati omiran si ailọlá. Bi ẹnikẹni ba wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́ kuro ninu wọnyi, on ó jẹ ohun èlo si ọlá, ti a yà si ọ̀tọ, ti o si yẹ fun ìlo bãle, ti a si ti pèse silẹ si iṣẹ rere gbogbo. Mã sá fun ifẹkufẹ ewe: si mã lepa ododo, igbagbọ́, ifẹ, alafia, pẹlu awọn ti nkepè Oluwa lati inu ọkàn funfun wá.