II. Tes 3:11-13

II. Tes 3:11-13 YBCV

Nitori awa gburo awọn kan ti nrin ségesège larin nyìn ti nwọn kò nṣiṣẹ rara, ṣugbọn nwọn jẹ àtọjú-ile-kiri. Njẹ irú awọn ẹni bẹ̃ li awa npaṣẹ fun, ti a si nrọ̀ ninu Oluwa Jesu Kristi, pe ki nwọn ki o mã fi ìwa pẹlẹ ṣiṣẹ, ki nwọn ki o si mã jẹ onjẹ awọn tikarawọn. Ṣugbọn ẹnyin, ará, ẹ máṣe ṣãrẹ̀ ni rere iṣe.