DAFIDI si bere pe, ọkan ninu awọn ẹniti iṣe idile Saulu kù sibẹ bi? ki emi ki o le ṣe ore fun u nitori Jonatani. Iranṣẹ kan si ti wà ni idile Saulu, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Siba. Nwọn si pè e wá sọdọ Dafidi, ọba si bere lọwọ rẹ̀ pe, Iwọ ni Siba bi? O si dahùn wipe, Iranṣẹ rẹ ni. Ọba si wipe, Kò ha si ọkan ninu idile Saulu sibẹ, ki emi ki o ṣe ore Ọlọrun fun u? Siba si wi fun ọba pe, Jonatani ní ọmọ kan sibẹ ti o ya arọ. Ọba si wi fun u pe, Nibo li o gbe wà? Siba si wi fun ọba pe, Wõ, on wà ni ile Makiri, ọmọ Ammieli, ni Lodebari. Dafidi ọba si ranṣẹ, o si mu u lati ile Makiri ọmọ Ammieli lati Lodebari wá. Mefiboṣeti ọmọ Jonatani ọmọ Saulu si tọ̀ Dafidi wá, o si wolẹ niwaju rẹ̀, o si bu ọla fun u. Dafidi si wipe, Mefiboṣeti. On si dahùn wipe, Wo iranṣẹ rẹ! Dafidi si wi fun u pe, Máṣe bẹ̀ru: nitoripe nitotọ emi o ṣe ore fun ọ nitori Jonatani baba rẹ, emi o si tun fi gbogbo ilẹ Saulu baba rẹ fun ọ: iwọ o si ma ba mi jẹun nigbagbogbo ni ibi onjẹ mi.
Kà II. Sam 9
Feti si II. Sam 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Sam 9:1-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò