Ṣugbọn nigbati awọn Filistini gbọ́ pe, nwọn ti fi Dafidi jọba lori Israeli, gbogbo awọn Filistini si goke wá lati wa Dafidi; Dafidi si gbọ́, o si sọkalẹ lọ si ilu odi. Awọn Filistini si wá, nwọn si tẹ́ ara wọn li afonifoji Refaimu. Dafidi si bere lọdọ Oluwa, pe, Ki emi ki o goke tọ̀ awọn Filistini bi? iwọ o fi wọn le mi lọwọ bi? Oluwa si wi fun Dafidi pe, Goke lọ: nitoripe, dajudaju emi o fi awọn Filistini le ọ lọwọ. Dafidi si de Baal-perasimu, Dafidi si pa wọn nibẹ, o si wipe, Oluwa ti ya lù awọn ọtá mi niwaju mi, gẹgẹ bi omi iti ya. Nitorina li on ṣe pe orukọ ibẹ na ni Baal-perasimu. Nwọn si fi oriṣa wọn silẹ nibẹ, Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si ko wọn.
Kà II. Sam 5
Feti si II. Sam 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Sam 5:17-21
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò