Fun alãnu ni iwọ o fi ara rẹ hàn li alãnu, ati fun ẹni-iduro-ṣinṣin li ododo ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni iduro-ṣinṣin li ododo. Fun oninu-funfun ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni funfun: ati fun ẹni-wiwọ ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni wiwọ. Awọn enia ti o wà ninu iyà ni iwọ o si gbàla: ṣugbọn oju rẹ wà lara awọn agberaga, lati rẹ̀ wọn silẹ. Nitori iwọ ni imọlẹ mi, Oluwa: Oluwa yio si sọ okunkun mi di imọlẹ. Nitori nipa rẹ li emi ti là arin ogun kọja: nipa Ọlọrun mi emi ti fò odi kan. Pipe li Ọlọrun li ọ̀na rẹ̀; ọ̀rọ Oluwa li a ti dan wò: on si ni asà fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹle e. Nitori tani iṣe Ọlọrun, bikoṣe Oluwa? tabi tani iṣe apáta, bikoṣe Ọlọrun wa? Ọlọrun alagbara li o fun mi li agbara, o si sọ ọ̀na mi di titọ́. O ṣe ẹsẹ mi bi ẹsẹ agbọnrin: o si mu mi duro ni ibi giga mi. O kọ ọwọ́ mi ni ogun jijà; tobẹ̃ ti apá mi fà ọrun idẹ. Iwọ si ti fun mi li asà igbala rẹ: irẹlẹ rẹ si ti sọ mi di nla. Iwọ si sọ itẹlẹ mi di nla li abẹ mi; tobẹ̃ ti ẹsẹ mi kò fi yọ̀. Emi ti lepa awọn ọta mi, emi si ti run wọn; emi kò pẹhinda titi emi fi run wọn. Emi ti pa wọn run, emi si ti fọ́ wọn, nwọn kò si le dide mọ: nwọn ṣubu labẹ ẹsẹ mi. Iwọ si ti fi agbara di mi li amure fun ijà: awọn ti o ti dide si mi ni iwọ si ti tẹ̀ li ori ba fun mi. Iwọ si mu awọn ọta mi pẹhindà fun mi, emi si pa awọn ti o korira mi run. Nwọn wò, ṣugbọn kò si ẹnikan lati gbà wọn; nwọn wò Oluwa, ṣugbọn kò da wọn lohùn. Nigbana ni emi si gun wọn wẹwẹ bi erupẹ ilẹ, emi si tẹ̀ wọn mọlẹ bi ẹrẹ̀ ita, emi si tẹ wọn gbọrọ. Iwọ si gbà mi kuro lọwọ ijà awọn enia mi, iwọ pa mi mọ ki emi ki o le ṣe olori awọn ajeji orilẹ-ède: awọn enia ti emi kò ti mọ̀ yio ma sìn mi. Awọn alejo yio fi ẹ̀tan tẹriba fun mi: bi nwọn ba ti gbọ́ iró mi, nwọn o si gbọ́ ti emi. Ìpaiyà yio dé bá awọn alejo, nwọn o si ma bẹ̀ru nibi kọ́lọfin wọn. Oluwa mbẹ; olubukun si ni apata mi: gbigbega si li Ọlọrun apata igbala mi. Ọlọrun li ẹniti ngbẹsan mi, ati ẹniti nrẹ̀ awọn enia silẹ labẹ mi. On ni o gbà mi kuro lọwọ awọn ọta mi: iwọ si gbe mi soke ju awọn ti o dide si mi lọ: iwọ si gbà mi kuro lọwọ ọkunrin ìwa agbara. Nitorina emi o fi ọpẹ fun ọ. Oluwa, larin awọn ajeji orilẹ-ède: emi o si kọrin si orukọ rẹ. On ni ile-iṣọ igbala fun ọba rẹ̀: o si fi ãnu hàn fun ẹni-ami-ororo rẹ̀; fun Dafidi, ati fun iru-ọmọ rẹ̀ titi lailai.
Kà II. Sam 22
Feti si II. Sam 22
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Sam 22:26-51
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò