Ogun si tun wà larin awọn Filistini ati Israeli; Dafidi si sọkalẹ, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, o si ba awọn Filistini jà: o si rẹ̀ Dafidi. Iṣbi-benobu si jẹ ọkan ninu awọn òmirán, ẹniti òṣuwọn ọ̀kọ rẹ̀ jẹ ọdunrun ṣekeli idẹ, on si sán idà titun, o si gbero lati pa Dafidi. Ṣugbọn Abiṣai ọmọ Seruia si ràn a lọwọ, o si kọlu Filistini na, o si pa a. Nigbana ni awọn iranṣẹ Dafidi si bura fun u, pe, Iwọ kì yio si tun ba wa jade lọ si ibi ija mọ, ki iwọ ki o máṣe pa iná Israeli. O si ṣe, lẹhin eyi, ija kan si tun wà lãrin awọn Israeli ati awọn Filistini ni Gobu: nigbana ni Sibbekai ara Huṣa pa Safu, ẹniti iṣe ọkan ninu awọn òmirán. Ija kan si tun wà ni Gobu lãrin awọn Israeli ati awọn Filistini, Elhanani ọmọ Jairi ara Betlehemu si pa arakunrin Goliati ara Gati, ẹniti ọpá ọ̀kọ rẹ̀ dabi idabú igi ti a fi hun aṣọ. Ija kan si tun wà ni Gati, ọkunrin kan si wà ti o gùn pupọ, o si ni ika mẹfa li ọwọ́ kan, ati ọmọ-ẹsẹ mẹfa li ẹsẹ kan, apapọ̀ rẹ̀ si jẹ mẹrinlelogun; a si bi on na li òmirán. Nigbati on si pe Israeli ni ijà, Jonatani ọmọ Ṣimei arakunrin Dafidi si pa a. Awọn mẹrẹrin wọnyi li a bi li òmirán ni Gati, nwọn si ti ọwọ́ Dafidi ṣubu, ati ọwọ́ awọn iranṣẹ rẹ̀.
Kà II. Sam 21
Feti si II. Sam 21
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Sam 21:15-22
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò