Nwọn wá, nwọn si do tì i ni Abeli ti Betmaaka, nwọn si mọdi tì ilu na, odi na si duro ti odi ilu na: gbogbo enia ti mbẹ lọdọ Joabu si ngbiyanju lati wó ogiri na lulẹ. Obinrin ọlọgbọ́n kan si kigbe soke lati ilu na wá, pe, Fetisilẹ, fetisilẹ, emi bẹ̀ nyin, sọ fun Joabu pe, Sunmọ ihinyi emi o si ba ọ sọ̀rọ. Nigbati on si sunmọ ọdọ rẹ̀, obinrin na si wipe, Iwọ ni Joabu bi? on si dahùn wipe, Emi na ni. Obinrin na si wi fun u pe, Gbọ́ ọ̀rọ iranṣẹbinrin rẹ. On si dahun wipe, Emi ngbọ́. O si sọ̀rọ, wipe, Nwọn ti nwi ṣaju pe niti bibere, nwọn o bere ni Abeli: bẹ̃ni nwọn si pari ọ̀ran na. Emi li ọkan ninu awọn ẹni alafia ati olõtọ ni Israeli: iwọ nwá ọ̀na lati pa ilu kan run ti o jẹ iyá ni Israeli: ẽṣe ti iwọ o fi gbe ini Oluwa mì?
Kà II. Sam 20
Feti si II. Sam 20
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Sam 20:15-19
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò