II. Sam 17:5-7

II. Sam 17:5-7 YBCV

Absalomu si wipe, Njẹ̀ pe Huṣai ará Arki, awa o si gbọ́ eyi ti o wà li ẹnu rẹ̀ pẹlu. Huṣai si de ọdọ Absalomu, Absalomu si wi fun u pe, Bayi ni Ahitofeli wi, ki awa ki o ṣe bi ọ̀rọ rẹ̀ bi? bi kò ba si tọ bẹ̃, iwọ wi. Huṣai si wi fun Absalomu pe, Imọ̀ ti Ahitofeli gbà nì, ko dara nisisiyi.