Dafidi si wá si Mahanaimu. Absalomu si goke odo Jordani, on, ati gbogbo awọn ọkunrin Israeli pẹlu rẹ̀.
Absalomu si fi Amasa ṣe olori ogun ni ipò Joabu: Amasa ẹniti iṣe ọmọ ẹnikan, orukọ ẹniti a npè ni Itra, ara Israeli, ti o wọle tọ Abigaili ọmọbinrin Nahaṣi, arabinrin Seruia, iyá Joabu.
Israeli ati Absalomu si do ni ilẹ Gileadi.
O si ṣe, nigbati Dafidi si wá si Mahanaimu, Ṣobi ọmọ Nahaṣi ti Rabba ti awọn ọmọ Ammoni, ati Makiri ọmọ Ammieli ti Lodebari, ati Barsillai ara Gileadi ti Rogelimu,
Mu akete, ati ago, ati ohun-elo amọ̀, ati alikama, ati ọkà, ati iyẹfun, ati agbado didin, ati ẹ̀wa, ati erẽ, ati ẹ̀wa didin.
Ati oyin, ati ori-amọ, ati agutan, ati wàrakasi malu, wá fun Dafidi, ati fun awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀ lati jẹ: nitoriti nwọn wi pe, ebi npa awọn enia, o si rẹ̀ wọn, orungbẹ si ngbẹ wọn li aginju.